BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Fídíò, Agboolé Akọni: Sodeke, jagunjagun tó kó àwọn aráàlú Egba àti adé wọ ilú Abeokuta, Duration 4,47
Lori Agboole Akoni ti ọtẹ yii, BBC Yoruba gbera lọ siluu Abeokuta, to jẹ olu ilu ipinlẹ Ogun lati lọ mọ nipa jagunjagun, to ko awọn ọmọ Egba wọ ilu Abeokuta, to si jẹ pe a le pe ni ẹni akọkọ to kọkọ tẹwọgba ẹsin Kristẹni niluu Abeokuta.
Ìjọba Osun ní ọlọ́pàá ń dúnkokò mọ́ òun, ọlọ́pàá ní kó mú ẹ̀rí wá
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ ni ijọba Osun ti sọ ọrọ naa.
"Òfin Sharia wà lára nǹkan tó ń fa ìṣekùpani Kristẹni ní Naijiria"
Awọn ọmọ orilẹede Naijiria, paapa lati apa ariwa, ti bu ẹnu atẹlu iroyin naa pe ko ni ẹsẹ nilẹ rara
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,01
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Ìjọba Kogi kéde kónílé-ó-gbélé láwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan nítorí ètò àbò tó mẹ́hé
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ alaga ijọba ibile iwọ oorun Yagba, Babarinde Sunday, fi lede lo ti fi idi iroyin naa mulẹ.
Gbogbo nǹkan tí mo ní láyé ni mo ná sórí àrùn túmọ̀ inú ọpọlọ, Bisola Badmus sọ̀rọ̀ lórí àìsàn tó fẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀
Ni mẹsan mẹwaa ni Badmus n dupẹ lọwọ Eledua fun oore ọfẹ to ri gba lati ṣe ọjọ ibi rẹ mii lẹyin ilakọja rẹ lori arun tumo inu ọpọlọ.
Àwọn afurasí tọ́wọ́ tẹ̀ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe pa òṣìṣẹ́ FRSC àti ọmọ rẹ̀ tí wọ́n jí gbé l'Ogun
Ẹni ọdun mejidinlogoji ni wọn pe Lasisi Oluwamayokun, nigba ti ọmọ rẹ, Lasisi Sewa jẹ ọmọ ọdun mejila.
Ìjọba gbọ́dọ̀ ní àkójọpọ̀ orúkọ gbogbo aráàlú lórí ẹ̀rọ kọ̀mpútà tó bá fẹ́ rẹ́yìn ìgbésùnmọ̀mí - Christopher Musa
Ninu lẹta ti Tinubu fi ṣọwọ si aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, fun ibuwọlu ni aarẹ ti ṣalaye pe Musa ni yoo rọpo Alhaji Mohammed Badaru Abubakar minisita eto aabo tẹlẹ to kọwe fipo silẹ lọjọ Aje.
Báǹkì àgbà ilẹ̀ wa, CBN, mú àdínkù bá owó gbígbà síta
Igbesẹ tuntun yii ni yoo wọgile eyi to ti wa ni ilẹ tẹlẹ, to fun awọn araalu ni anfani lati gba owo toto milọnu marun un sita lọsẹ, ti awọn ileeṣẹ si le gba milọnu mẹwaa sita.
Ọba Famodun kì í ṣe ọba ìlú Igbajo, agbára ní Oyetola lò lé wa lórí -Àwọn afọbajẹ
Oloye Olalekan Ogunmoyede, ẹni to jẹ olori awọn afọbajẹ iluu Igbajọ ba BBC news Yoruba sọrọ lori awọ to da rogbodiyan silẹ niluu naa.
Kí ló dé tí ìjọba US ṣe fẹ́ dènà físà àwọn ọmọ Naijiria kan, òṣìṣẹ́ ìjọba àti ẹbí wọn?
Akọwe ijọba, Marco Rubio ni pe ile ijọba Washington n gbe igbesẹ yii lori aṣẹ Aarẹ Trump lati gbe ogun ti awọn eeyan kan ti wọn lọwọ ninu kiko ogun ja ati iṣekupani awọn Kristẹni ni Naijiria ati kaakiri agbaye."
Ìjọba kéde fífi òfin de lílo ojú òpó ayélujára fáwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún mẹ́rìndínlógún, ìdí rèé
Ìjọba Australia ní ìgbésẹ̀ fífi òfin de àwọn ojú òpó yìí, èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn obí faramọ́, jẹ́ ojúnà láti mú àdínkù bá ìpèníjà táwọn ọmọdé ń kojú lójú òpó ayélujára
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Ọkùnrin tó jí ara rẹ̀ gbé láti gba owó lọ́wọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ l'Ondo dèrò àtìmọ́lé
Mathew Ekele ni ọwọ tẹ niluu Ogbese to wa loju ọna marosẹ ilu Akure siluu Owo.
Igun PDP kan kéde Adebayo Adedamola gẹ́gẹ́ bíi olùdíje gómìnà l'Osun
Gomina Ademola Adeleke ko tii kede ẹgbẹ oṣelu ti yoo darapọ mọ bayii, lẹyin to fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.
Ijó, ayọ̀ báwọn èèyàn 38 tí wọ́n jí gbé ní Eruku ṣe padà sílé
Irọlẹ oni, ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni Aarẹ Tinubu kede bẹẹ loju opo X rẹ.
Iye ìgbà tí Sowore ti dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tó gbéná wojú ìjọba Naijiria
Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti sọ pe oun yoo wọgile beeli to fun Omoyele Sowore to ba tun pada sọ ọrọ ti wọn gbagbọ pe o le da omi alaafia Naijiria ru.
Kókó àbájáde ìwádìí àwọn aṣòfin Amẹrika lórí ọ̀rọ̀ tí Trump sọ pé ìpanirun àwọn Kristẹ́nì ń ṣẹlẹ̀ ní Naijiria
Brian Mast to n ri sọrọ ilẹ okeere sọ pe ko si nnkan to jọ ija ileto kan si omiran ninu nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria bayii, Mast ni awọn to n ṣe ikọlu yii mọọmọ fẹ pawọn kristẹni run lori ilẹ ati nile wọn ni.
Fídíò, Kí ló fà á tí ọ̀nà Circular Road n'Ibadan tó yẹ kó mú inú aráàlú dùn ṣe ń gba omijé lójú wọn?, Duration 2,46
Ọpọ awọn olugbe ijọba ibilẹ mẹfa ni ilu Ibadan, olu ilu Ipinlẹ Oyo ni wọn fi ehonu han loni ọjọ Aje ọjọ kẹwaa oṣu kọkonla ọdun 2025 lori bi ijọba Ipinlẹ Oyo se n wo dukia won lulẹ.
Àwọn ajínigbé fún ìlú ní ọ̀sẹ̀ kan láti san 300m owó ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n jí gbé, tàbí kí wọ́n padà wá láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ aráàlú
Ko tan si bẹ o, ṣe ni wọn tun fun ilu naa ni gbendeke ọsẹ kan lati san owo yii tabi ki wọn pa gbogbo awọn ti wọn ji gbe.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Edo ní kí ìyàwó Tuface, Natasha Osawaru, wáá ṣàlàyé ara rẹ̀, ìdí rèé
Natasha ti ifẹ oun ati Tuface gbode lojiji, ni aṣofin to n ṣoju ẹkun Egor, nipinlẹ Edo.
PDP fi ìwé ẹ̀rí yíyọ kúrò nínú ẹgbẹ́ ránṣẹ́ sí Wike, Fayose àti àwọn yòókù
Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ oṣelu PDP, lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kọkanla lasiko ipade apero, fọwọ osi juwe ile fun Wike ati awọn yooku lori ẹsun pe wọn n ditẹ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Olórí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò kú sí àhámọ́ lẹ́yìn oṣù kan
Anicet Ekane to ku si ahamọ yii jẹ ọkan lara awọn to ṣe atileyin fun Issa Tchiroma Bakary, alatako Aarẹ Paul Biya, ninu ibo to wa ye loṣu Kẹwaa ọdun yii.
Ogbomoso Parapo: Bí ìgbẹ́jọ́ láàárín Soun àtàwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ ṣe lọ rèé
Ilé ẹjọ́ tún ṣe ìdádúró àwọn aláṣẹ fìdíẹ́ tí Ọba Ghandi yàn láti yé pe ara wọn ní aláṣẹ ẹgbẹ́ náà títí tí ìgbẹ́jọ́ fi máa wáyé ní oṣù Kìíní ọdún 2026.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Kí ló fà á tí Owa ìlú Igbajo fi pé méjì èyí tó fa rògbòdìyàn lẹ́yìn ìpapòdà Ọba Famodun?
Eni ọdun mẹtadinlaadọrun ni Ọba Famodun ko to jade laye.
Ṣé ọmọ bíbí lè dín iye ọjọ́ tó yẹ kí obìnrin lò lókè eèpẹ̀ kù?
Iwadii kan ti fi han pe bi eeyan ṣe n bi ọmọ si le maa yọ oṣu mẹfa lara obinrin.
Ìwakùsà lọ́nà àìtọ́ ló ń ṣokùnfà ètò àbò tó mẹ́hẹ lọ́dọ̀ wa, a fẹ́ kí Ààrẹ gbẹ́sẹ̀le – Àwọn gómìnà Àríwá
Ipade naa ti awọn ori ade agbegbe naa yọju si ni wọn ti fẹnuko pe ki wọn maa ko owo ti iye rẹ to biliọnu kan naira jọ loṣoṣu fun eto abo agbegbe naa.
"Ẹ wo bí ẹ̀rí èké tí mo jẹ́ nílé ẹjọ́ ṣe sọ ọ̀dọ́ mẹ́ta tí kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn dèrò ẹ̀wọ̀n ódún 36"
Bishop ni niṣe loun n gbọn nigba ti wọn ni koun wa jẹrii nile ẹjọ tori nnkan ti ko ṣẹlẹ ni wọn sọ pe koun maa sọ.
Ẹ wo bí onírúurú ẹbí ṣe ń fi okòwò tata rán àwọn ọmọ wọn nílé ẹ̀kọ́, gbọ́ bùkátà
Ṣiṣe odẹ tata ti wọn maa n pe ni Mungwin ni ede Cameroon jẹ nnkan to ti di aṣa nilẹ naa, o si jẹ ọrọ aje fun ọpọ eeyan níbẹ.
Àwọn ajínigbé jí Ọba gbé ní Kwara, bèèrè N150m owó ìtúsílẹ̀
Nnkan bi ago mẹsan an abọ owurọ ọjọ Satide ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti Oba, Ojibara ti ilu Bayangan, Alhaji Kamilu Salami n lọ sinu oko rẹ.






























































